Awa l'agbejoro fun igboro.
Ti ko ba si temi, ijoba ma s'ojoro.
Lowo yii, emi gaan tiwa gboro.
Tan ba fe yan waje, Ilu yi koni toro.
Bi ijoba fun mi, emi koni gba owo.
Lowo yi, mo ti di ada oloro.
Leke-leke ni mi, mi o le wo aso aro.
Emi o so otito, onpe koju yin to faro!
Omo ogun ni mi, kilo kan mi pelu
'shayo'.
Oju eje mo wa, emi kole fa 'claro.'
Lori otito, mo le so oke di odo.
Ilu yi ajoro ti ko ba si ododo.
Mo ti mu iberu kuro,
ododo ni mo ba duro.
Owo mi mo bi ti poro,
funfun ni ko s'ororo!
Mi o kin se ologogoro...
lowo ijoba emi koni tirogo!
Ni ti otito, emi ko jisoro...
baba mi, ododo lo se koko.
Lanre badmus
June 2018
Comments